
ADEGBONMIRE D’OMO OYEKU MEJI, ADENIYI TI DI IKIN LATI ONI LO….
* OTAGBALE Awo Ile Alara ,
* ARINGBALE Awo Oke Ijero,
*ONAGBAKEKEWOJA Awo won nile Owarangun Aga,
Awon meteeta lo difa fun OYEKU MEJI
Lojo ti Baba nbe larin awon ota
Baba nbe larin awon abenilori
Baba nbe larin awon panipani
Oyeku meji ni oun yio di omo eja, won ni iwo oyeku meji
Won ni o momo di omo eja
Won ni tori awon adegiri nbe lodo, omo eja ni won npa kiri.
Oyeku meji ni oun yio di omo ata
Woni iwo oyeku meji
Woni o momo di omo ata
Won ni tori awon igba nbe lona
Omo ata ni won npa kiri
Oyeku meji tun l’oun yio di omo eye, won ni iwo oyeku meji won ni o momo di omo eye, won ni tori awon afa kana-kanaa nbe lona omo eye niwon npa kiri,
Oyeku meji tun wa l’oun yio di omo Esisi,
Won ni iwo oyeku meji
Won ni o momo di omo esisi
Won ni tori awon igba owo(broom) nbe lona , omo esisi ni won npa kiri
Otagbale Aringbale Onagbakenke woja*
Adifa fun oyeku meji lojo ti
Baba nbe larin awon ota
Baba nbe larin awon asenilori
Baba nbe larin awon panipani
Oyeku meji wan ni oun yio di ikin wayi o, won ni iwo oyeku meji , se kankan , mura koo di ikin
Nitori kinni, nitori pe
Ori o ki nfo ikin
Edo kii rin Igbin
Ororo kii ro ojee
Otutu kan kii meja nisale odo
N Lo ba s’enu koto n ni
Orin awo ba bosi Omo Awo lenu
🎼 wa wa ni “mo fori balee modi ikin oo, mofori bale mo di ikin,
Ori kii fokin
Ororo oroje
Mo fori bale modi ikin,
Gbogbo Ota e wa fori bale f’oyekuu, mo fori bale mo di Ikinnnnnnn!!!!!!……”
OMO ADEGBONMIRE O TI DI IKIN OOOO X2,
GBOGBO OTA E WA F’ORIBALE F’ ADENIYI .
Aboru aboye nile Awo Ooooo
OTUNBA TIFASE LATI ILU AKURE, Oloyemekun.














Leave a Reply