FREEDOM REPORTERS

UNDILUTED NEWS AND UPDATES

OKIN DEEEE… OLOJA EYE !!!

OKIN DEEEE… OLOJA EYE !!!

“………Ori mi Afireee,
“Ori lo se ti ALARA f’alara to fi se tire to gun repete…..,
Ori lo ba AJERO fikun l’ukun ti AJERO fi n tipa Ileke
Ori lo se ti ORANGUN ile ILA Omo Ageshin j’agun ti baba fi di Oloro lawujo gbogbo Oba….., “.
A D’ifa fun eye Okin l’ojo ti won ni yio j’oloja lawujo awon Eye…………, ( Consult elders for more details).

Okin lo ba gbo riru Ebo o ru….,
Okin gbo titu Etutu o tu……,
Okin ko p’awo l’eke, ko p’esu Odara l’ole, ko p’awon iya oshoronga ni “Amuniyun-oja m’uni ra’hun je”…..,

Oro Okin ba d’ijo, Oro Okin ba d’ayo…,
“… Ijo L’eye Okin wa n Jo, Ayo L’eye Okin n yo…, Omo Elebo n yin Babalawo, Babalawo wa n yin IFA.., IFA wa n yin Olodumare koro-koro lode Orun……”

Hin lo ba ya l’orin Awo ba bo koto s’omo Awo l’enu…., Ni won wa n korin wipe :

“…..Okin dee hee, OLOJA EYE…..,
Okin de ooooo hoo , OLOJA EYE ooo…,
E wo ile Ire , E F’okin Wo oooo…….”

OKIN TI DE…,
OLOJA EYE DE..,

# OLOGEDE FOR MHA2027 AKURE NORTH CONSTITUENCY #

@ OTUNBA TIFASE

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *